[go: up one dir, main page]

Jump to content

Colin Powell

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ọ̀gágun

Colin Luther Powell
65th Alakoso Oro Okere ile Amerika
In office
January 20, 2001 – January 26, 2005
ÀàrẹGeorge W. Bush
DeputyRichard Armitage
AsíwájúMadeleine Albright
Arọ́pòCondoleezza Rice
12th
In office
October 1, 1989 – September 30, 1993
ÀàrẹGeorge H. W. Bush
Bill Clinton
DeputyRobert T. Herres (1989)
David E. Jeremiah (1989-1993)
AsíwájúWilliam J. Crowe
Arọ́pòDavid E. Jeremiah
16th
In office
1987–1989
ÀàrẹRonald Reagan
DeputyJohn Negroponte
AsíwájúFrank Carlucci
Arọ́pòBrent Scowcroft
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí5 Oṣù Kẹrin 1937 (1937-04-05) (ọmọ ọdún 87)
New York City, New York, U.S.A.
Ẹgbẹ́ olóṣèlúRepublican
(Àwọn) olólùfẹ́Alma Vivian Johnson Powell
Alma materCity College of New York
George Washington University
ProfessionSoldier
Statesman
Military service
AllegianceUnited States of America
Branch/serviceArmy
Years of service1958-1993
RankGeneral
Unit3rd Armored Division
Americal Division
CommandsForces Command
Battles/warsVietnam War
Invasion of Panama
Gulf War

Colin Luther Powell ti won bi (ọjọ́ìbí 5 April, 1937 - Oṣu Kẹwa ọjọ 18, ọdun 2021) jẹ́ ẹni àyẹ́sí ọmọ ilẹ̀ Améríkà àti Ọ̀gágun oníràwò mérin to ti fèyìntì kúrò ní Ilé-isé Ológun Jagunjagun ilè Améríkà. O tun jé Alákòso Òrò Òkèrè ilè Améríkà láti 2001 - 2005 lábé Ààrẹ George W. Bush. Ohun ni ẹni aláwòdúdú àkókó ti yio gun orí ipò yi.[1][2][3][4] Nígbàtí wa ni ẹnu isé ológun, Powell tún je Alábàágbìmọ̀pọ̀ Ọ̀rọ̀ Àbò Orílẹ́-èdè ile Améríkà (National Security Advisor, 1987-1989); Apèse, Ilé-isé Alase àwọn Ológun Jagunjagun ilè Améríkà (U.S. Army Forces Command, 1989); àti Alaga Ijokopápo àwọn Ògá Ọmọ-ológun ilè Améríkà (Chairman, U.S. Joint Chiefs of Staff, 1989-1993), orí ipò yi lówà nígbàtí Ogún Ikùn Odò Persia selè. Ohun ni o jẹ́ ẹni aláwòdúdú àkókó, àti soso títí dòní, ti yio kópa nínú Ijokopapo àwọn Ògá Ọmọ-ológun ilè Améríkà (Joint Chiefs of Staff).

A bí Colin Luther Powell ni ọjọ́ 5 osù kerin odún 1937 ní Harlem to jẹ àdúgbò kan ní ìlú New York fún Luther Theophilus Powell àti Maud Arial McKoy ti wọn ko wá sílè láti ilè Jamaika. O si dàgbà ní South Bronx. Apá àwọn òbí re kan tún wa láti ilè Skotlandi àti Irelandi. Powell lo si ilé èkó Morris High School to fi ìgbà kan jẹ ti ìgboro ní Bronx, o parí níbẹ̀ ní 1954.

Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ní Ilé-iṣẹ́ Ológun

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Powell darapo mo Reserve Officers' Training Corps ni ilè èkó City College ní New York o si sàlàyé re léyìn ìgbà na gẹ́gẹ́ bi ìrírí tí o mu inu re dunjulo laye re, pe ohun ti ri ohun ti ohun fẹ́ràn tí ohun si mọ̀ọ́ ṣe, lókàn re pe "öhun ti wa ara ohun ri." Gẹ́gẹ́ bi Kèdẹ́ẹ̀tì, Powell darapò mo ẹgbẹ́ àwọn Ayìnbọn Pershing ní City College. Nígbàtó parí èkó re ní City College ní 1958, ó gbà ipò gẹ́gẹ́ bi igbákẹ̀ta ajagun ní Ilé-isé Ológun Jagunjagun ilè Améríkà (second lieutenant, United States Army).[5] Òṣìṣé ọmọ-ogun lo jẹ fún odún 35, o di orísirísi Ilé-isé apèse àti ipò alábàṣiṣépò mú títí to fi gòkẹ̀ dè ipò Ògágun ní 1989.[6]


Ọjọ́ọdún tó dé àwọn ipò rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • Igbákẹta Ajagun (Second Lieutenant): June 9, 1958
  • Igbákejì Ajagun (First Lieutenant}: December 30, 1959
  • Ajagun Ile-ise Ologun Jagunjagun ile Amerika (Captain, U.S Army): June 2, 1962
  • Àgbàogun (Major): May 24, 1966
  • Igbákejì Akógun (Lieutenant Colonel): July 9, 1970
  • Akógun (Colonel): February 1, 1976
  • Ọ̀gágun Ẹlẹ́ẹ̀ṣọ́ (Brigadier General): June 1, 1979
  • Ọ̀gágun Àgbàogun (Major General): August 1, 1983
  • Igbákejì Ọ̀gágun (Lieutenant General): March 26, 1986
  • Ọ̀gágun (General): April 4, 1989


Àwọn ìgbésókè
Okùn Ipò Ọjọ́ọdún
ỌGG-GEN 1989
IỌG-LTG 1986
ỌA-MG 1983
ỌẸ-BG 1979
AKO-COL 1976
IAK-LTC 1970
AO-OMAJ 1966
AJA-CPT 1962
2AJA-1LT 1959
3AJA-2LT 1958

Àwọn Ebun àti eye

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Awọn ìlẹ̀máyà

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Alábàágbìmọ̀pọ̀ Ọ̀rọ̀ Àbò Orílẹ́-èdè

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Nigbato di omo odun 49, Powell di Alábàágbìmọ̀pọ̀ Ọ̀rọ̀ Àbò Orílẹ́-èdè fún Àare Ronald Reagan lati 1987 titi di 1989 lai fi ipò re sílè gẹ́gẹ́ bi igbákejì ògágun (lieutenant general). Nígbàtó parí isé Ìgbìmò Òrò Àbò ilè Améríkà, Powell gbà ìgbésókè si ipò Ògágun lábé Àare George H.W. Bush, o si ṣiṣé nígbà die gẹ́gẹ́ bi Alásẹ, Ilé-isé Apèse àwọn Ológun Jagunjagun ilè Améríkà, to un mójútó gbogbo Ológun Jagunjagun, Ológun Jagunjagun Alágbẹ́pamó, àti àwọn ẹyo Ilé-isé Ológun Olúsọ́ ilè Améríkà (U.S. National Guard) fun orile Améríkà, Alaska, Hawaii àti Puerto Rico.

Alága Ijókopapo àwọn Oga Omo-ologun

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àfúnse isé ológun to se gbèyìn, láti October 1, 1989 títí di September 30, 1993 ní gẹ́gẹ́ bí Alága ìkejìlá Ijókopapo àwọn Ògá Ọmọ-ológun, èyí ni ipò ológun tógajúlo ní Ilé-isé Alákòso Òrò-àbò ilè Améríkà (U.S. Dept. of Defense).

  1. The first Áfríkà Améríkà secretary of state, Colin Powell Archived 2008-06-04 at the Wayback Machine., The African American Registry
  2. Biographies - Colin Powell: United States Secretary of State, African American History Month, US Department of Defense
  3. Colin Powell, Britannica Online Encyclopedia
  4. Profile: Colin Powell, BBC News
  5. "Secretary of State Colin L. Powell (biography)". The White House. 2003-04-29. Retrieved 2007-02-03. 
  6. "Colin (Luther) Powell Biography (1937 - )". The Biography Channel. A&E Television Networks. Archived from the original on 2007-08-07. Retrieved 2007-05-31. 


Ìwé kíkà lẹ́kùnréré

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn Ìjápò Íntérnétì

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Wikiquote logo
Wikiquote logo
Nínú Wikiquote a ó rí ọ̀rọ̀ tójẹmọ́:
Wikisource has original text related to this article:
Wikinews ní ìròhìn lórí ọ̀rọ̀ yíì: